Deuteronomy 12:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun bá jìnnà pupọ sí yín, ẹ mú mààlúù tabi aguntan láti inú agbo ẹran tí OLUWA fi fun yín, kí ẹ pa á bí mo ti pa á láṣẹ fun yín, kí ẹ sì jẹ ohunkohun tí ọkàn yín bá fẹ́ láti jẹ láàrin àwọn ìlú yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ba ṣepe, ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ ba yàn, lati fi orukọ rẹ̀ si, ba jìna jù fun ọ, njẹ ki iwọ ki o pa ninu ọwọ́-ẹran rẹ ati ninu agbo-ẹran rẹ, ti OLUWA fi fun ọ, bi emi ti fi aṣẹ fun o, ki iwọ ki o si ma jẹ ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́ ninu ibode rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ibi tí OLÚWA Ọlọ́run yín bá yàn fún orúkọ rẹ̀ bá jìnnà sí i yín, kí ẹ pa màlúù tàbí ewúrẹ́ tí OLÚWA Ọlọ́run yín tí fún un yín, bí mo ti pàṣẹ fún un yín ní ìlú u yín, ẹ lè jẹ ẹ́ bí ẹ ti fẹ́.