Deuteronomy 12:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ kíyèsára, kí ẹ rí i dájú pé ẹ pa àwọn ohun tí mo pa láṣẹ fun yín mọ́, kí ó lè dára fún ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesara ki o si ma gbọ́ gbogbo ọ̀rọ wọnyi ti mo palaṣẹ fun ọ, ki o le dara fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lẹhin rẹ lailai, nigbati iwọ ba ṣe eyiti o dara ti o si tọ́ li oju OLUWA Ọlọrun rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ kíyèsára láti máa gbọ́ràn sí gbogbo ìlànà tí mò ń fún un yín, kí o báà dára fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín nígbà gbogbo, nítorí pé nígbà náà ní ẹ tó ń ṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà níwájú OLÚWA Ọlọ́run yín.