Deuteronomy 12:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ kò gbọdọ̀ sin OLUWA Ọlọrun yín bí wọn ti ń bọ àwọn oriṣa wọn nítorí oríṣìíríṣìí ohun tí ó jẹ́ ìríra lójú OLUWA ni wọ́n máa ń ṣe. Wọn a máa fi àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin wọn rúbọ sí oriṣa wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ kò gbọdọ ṣe bẹ̃ si OLUWA Ọlọrun rẹ; nitoripe gbogbo ohun irira si OLUWA, ti on korira ni nwọn ti nṣe si awọn oriṣa wọn; nitoripe awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin wọn pẹlu ni nwọn nsun ninu iná fun oriṣa wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ má ṣe sin OLÚWA Ọlọ́run yín bí àwọn, torí pé, nípa sínsin ọlọ́run wọn, wọ́n ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìríra tí Ọlọ́run kórìíra. Wọ́n ń dáná ṣun àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn láti fi rúbọ sí ère òrìṣà wọn.