Deuteronomy 13:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ náà. Bí ó bá jẹ́ pé òtítọ́ ni, tí ó sì dáa yín lójú pé ohun ìríra bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ láàrin yín,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ki iwọ ki o bère, ki iwọ ki o si ṣe àwari, ki o si bère pẹlẹpẹlẹ; si kiyesi i, bi o ba ṣe otitọ, ti ohun na ba si da nyin loju, pe a ṣe irú nkan irira bẹ̃ ninu nyin;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹ wádìí, ẹ bèèrè, kí ẹ sì tọpinpin ọ̀rọ̀ náà dájúṣáká, bí ó bá jẹ́ òtítọ́ ni, tí ó sì hàn dájú pé ìwà ìríra yìí ti ṣẹlẹ̀ láàrin yín.