Deuteronomy 13:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
idà ni kí ẹ fi pa àwọn tí wọn ń gbé ìlú náà. Ẹ pa wọ́n run patapata, ati gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀; ẹ fi idà pa gbogbo wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ ki o fi oju idà kọlù awọn ara ilu na nitõtọ, lati run u patapata, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ati ohunọ̀sin inu rẹ̀, ni ki iwọ ki o fi oju idà pa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn tí ó ń gbé ìlú náà ni kí ẹ fi idà run pátápátá. Ẹ run ún pátapáta, àti ènìyàn àti ẹran ọ̀sìn inú rẹ̀.