Deuteronomy 13:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ìkógun yìí jẹ́ ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan èyíkéyìí ninu wọn kí OLUWA lè yí ibinu gbígbóná rẹ̀ pada, kí ó ṣàánú fun yín, kí ó sì mú kí ẹ pọ̀ sí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ọkan ninu ohun ìyasọtọ na má si ṣe mọ́ ọ lọwọ; ki OLUWA ki o le yipada kuro ninu imuna ibinu rẹ̀, ki o si ma ṣãnu fun ọ, ki o si ma ṣe iyọnu rẹ, ki o si ma mu ọ bisi i, bi o ti bura fun awọn baba rẹ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A kò gbọdọ̀ rí ọ̀kan nínú àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ fún ìparun wọ̀n-ọn-nì lọ́wọ́ ọ yín, kí OLÚWA ba à le yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀, yóò sì ṣàánú fún un yín, yóò sì bá a yín kẹ́dùn, yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i, bí ó ti fìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá yín.