Deuteronomy 13:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn pípa ni kí ẹ pa wolii tabi alálàá náà, nítorí pé ó ń kọ yín láti ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì rà yín pada kúrò ní oko ẹrú. Ẹ níláti pa olúwarẹ̀ nítorí pé ó fẹ́ mú kí ẹ kọ ẹ̀yìn sí ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín ti là sílẹ̀ fun yín láti máa rìn, nítorí náà ẹ gbọdọ̀ yọ nǹkan burúkú náà kúrò láàrin yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati wolĩ na, tabi alalá na, ni ki ẹnyin ki o pa; nitoriti o ti sẹ ọtẹ̀ si OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, ti o ti rà nyin kuro li oko-ẹrú, lati tì ọ kuro li oju ọ̀na ti OLUWA Ọlọrun rẹ filelẹ li aṣẹ fun ọ lati ma rìn ninu rẹ̀. Bẹ̃ni ki iwọ ki o si mú ibi kuro lãrin rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wòlíì náà tàbí alálàá náà ni kí ẹ pa, nítorí pé wàásù ìṣọ̀tẹ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run yín, tí ó mú yín jáde láti Éjíbítì wá, tí ó sì rà yín padà lóko ẹrú. Ó ti gbìyànjú láti fà yín kúrò lójú ọ̀nà tí OLÚWA Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín láti máa rìn. Ẹ gbọdọ̀ yọ ibi náà kúrò láàrin yín.