Deuteronomy 14:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrarẹ̀, ẹ lè fún àwọn àlejò tí ń gbé ààrin yín, kí ó jẹ ẹ́, tabi kí ẹ tà á fún àjèjì, nítorí pé, ẹ̀yin jẹ́ ẹni mímọ́ fún OLUWA Ọlọrun yín. “Ẹ kò gbọdọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ ninu wàrà ọmú ìyá rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti o tikara rẹ̀ kú: iwọ le fi i fun alejò ti mbẹ ninu ibode rẹ, ki on ki o jẹ ẹ; tabi ki iwọ ki o tà a fun ajeji: nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ má ṣe jẹ ohun tí ó ti kú sílẹ̀. Ẹ lè fún àwọn àjèjì tí ń gbé ní èyíkéyí nínú ìlú yín. Òun lè jẹ ẹ́ tàbí kí ẹ tà á fún àwọn àjèjì. Ṣùgbọ́n ènìyàn mímọ́ fún OLÚWA Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin jẹ́. Má ṣe ṣe ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.