Deuteronomy 14:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí àwọn ọmọ Lefi, tí wọn kò ní ìpín ati ohun ìní láàrin yín, ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó tí wọ́n wà ninu àwọn ìlú yín jẹ, kí wọ́n sì yó, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun yín ninu gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ọmọ Lefi, nitoriti kò ní ipín tabi iní pẹlu rẹ, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ ninu ibode rẹ, yio wá, nwọn o si jẹ nwọn o si yó; ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le bukún ọ ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ ti iwọ nṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí àwọn Léfì (tí kò ní ìpín tàbí ogún ti wọn) àti àwọn àlejò, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé ìlú yín lè wá, kí wọn sì jẹ kí wọn sì yó, kí OLÚWA Ọlọ́run rẹ leè bùkún fún ọ, nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.