Deuteronomy 14:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹlẹ́dẹ̀, lóòótọ́ ó ní ìka ẹsẹ̀, ṣugbọn kì í jẹ àpọ̀jẹ, nítorí náà, ó jẹ́ aláìmọ́ fun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fara kan òkú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ẹlẹdẹ̀, nitoriti o là bàta-ẹsẹ̀ ṣugbọn kò jẹ apọjẹ, alaimọ́ ni fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu ẹran wọn, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọwọkàn okú wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ àìmọ́; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ya pátakò ẹṣẹ̀, kì í jẹ àpọ̀jẹ, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú rẹ̀.