Deuteronomy 15:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ẹ óo ṣe máa ṣe ìdásílẹ̀ náà nìyí: ẹnikẹ́ni tí aládùúgbò rẹ̀, tíí ṣe arakunrin rẹ̀, bá jẹ ní gbèsè kò ní gba ohun tí aládùúgbò rẹ̀ jẹ ẹ́ mọ́, nítorí pé, a ti kéde ìdásílẹ̀ tíí ṣe ti OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀na ijọwọlọwọ na si li eyi: gbogbo onigbese ti o wín ẹnikeji rẹ̀ ni nkan ki o jọwọ rẹ̀ lọwọ; ki o ma ṣe fi agbara bère rẹ̀ lọwọ ẹnikeji rẹ̀, tabi lọwọ arakunrin rẹ̀; nitoriti a pè e ni ijọwọlọwọ OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni kí ẹ máa ṣe é: Gbogbo ẹni tí wọ́n jẹ ní gbéṣè gbọdọ̀ fojú fo gbésè tí ó ti yá ará Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀. Kò gbọdọ̀ béèrè ohun náà, lọ́dọ̀ ará Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀ tàbí lọ́dọ̀ arákùnrin rẹ̀: nítorí pé a ti kéde àkókò OLÚWA láti fojú fo gbésè.