Deuteronomy 16:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ máa ranti láti máa ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá fún OLUWA Ọlọrun yín ninu oṣù Abibu nítorí ninu oṣù Abibu ni ó kó yín jáde ní ilẹ̀ Ijipti, lálẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
IWỌ ma kiyesi oṣù Abibu, ki o si ma pa ajọ irekọja mọ́ si OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoripe li oṣù Abibu ni OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ lati ilẹ Egipti jade wa li oru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ kíyèsí oṣù Ábíbù, kí ẹ sì máa ṣe àjọ̀dún ìrékọjá ti OLÚWA Ọlọ́run yín, nítorí pé ní oṣù Ábíbù yìí ni ó mú un yín jáde ní Éjíbítì lóru.