Deuteronomy 16:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ óo máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹbinrin ati iranṣẹkunrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gbé àwọn ìlú yín; àwọn àlejò, àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó, tí wọ́n wà láàrin yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ lãrin rẹ, ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé yàn, lati fi orukọ rẹ̀ si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLÚWA Ọlọ́run yín ní ibi tí yóò yàn ní ibùgbé fún orúkọ rẹ̀: ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn ẹrú u yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn Léfì tí ó wà ní ìlú u yín, àti àwọn àlejò, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé àárin yín.