Deuteronomy 16:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ máa yọ̀, bí ẹ ti ń gbádùn àjọ̀dún yín, ẹ̀yin, ati àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin ati àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin yín, àwọn ọmọ Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, tí wọ́n wà ní àwọn ìlú yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ ki o si ma yọ̀ ninu ajọ rẹ, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ ninu ibode rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ máa yọ̀ ní àkókò àjọ̀dún un yín, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín, àti àwọn Léfì, àwọn àjòjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó tí ń gbé ní àwọn ìlú u yín.