Deuteronomy 16:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi se àsè yìí fún OLUWA Ọlọrun yín níbi tí OLUWA bá yàn pé kí ẹ ti máa jọ́sìn, nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun gbogbo èso yín, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ óo láyọ̀ gidigidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ijọ́ meje ni ki iwọ ki o fi ṣe ajọ si OLUWA Ọlọrun rẹ ni ibi ti OLUWA yio yàn: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ ni gbogbo asunkún rẹ, ati ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ, nitorina ki iwọ ki o ma yọ̀ nitõtọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi se ayẹyẹ fún OLÚWA Ọlọ́run yín ní ibi tí OLÚWA yóò yàn. Nítorí pé OLÚWA Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín ní gbogbo ìkórè e yín, àti ní gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ yín, ayọ̀ ọ yín yóò sì kún.