Deuteronomy 16:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu pẹlu ẹbọ náà; ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ ẹ́ pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà. Oúnjẹ náà jẹ́ oúnjẹ ìpọ́njú, nítorí pé ìkánjú ni ẹ fi jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti; ẹ óo sì lè máa ranti ọjọ́ náà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ní gbogbo ọjọ́ ayé yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ kò gbọdọ jẹ àkara wiwu pẹlu rẹ̀; ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu pẹlu rẹ̀, ani onjẹ ipọnju; nitoripe iwọ ti ilẹ Egipti jade wá ni kanjukanju: ki iwọ ki o le ma ranti ọjọ́ ti iwọ ti ilẹ Egipti jade wa, li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ má ṣe jẹ ẹ́ pẹ̀lú u àkàrà tí a fi ìwúkàrà ṣe, ṣùgbọ́n ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà ìpọ́njú, nítorí pé pẹ̀lú ìkánjú ni ẹ kúrò ní Éjíbítì: kí ẹ báà lè rántí ìgbà tí ẹ kúrò ní Éjíbítì ní gbogbo ọjọ́ ayé e yín.