Deuteronomy 16:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn kò gbọdọ̀ bá ìwúkàrà lọ́wọ́ yín, ati ní gbogbo agbègbè yín, fún ọjọ́ meje. Ẹran tí ẹ bá fi rúbọ kò gbọdọ̀ ṣẹ́kù ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kinni, títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki a má si ṣe ri àkara wiwu lọdọ rẹ li àgbegbe rẹ gbogbo ni ijọ́ meje; bẹ̃ni ki ohun kan ninu ẹran ti iwọ o fi rubọ li ọjọ́ kini li aṣalẹ, ki o máṣe kù di owurọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí a má ṣe rí ìwúkàrà ní ọ̀dọ̀ ọ yín nínú ilẹ̀ ẹ yín fún ọjọ́ méje. Ẹ má ṣe jẹ́ kí nǹkan kan sẹ́kù nínú ẹran tí ẹ ó fi rúbọ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní di àárọ̀ ọjọ́ kéjì.