Deuteronomy 16:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àfi ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun, níbẹ̀ ni ẹ ti gbọdọ̀ máa rú ẹbọ àjọ ìrékọjá ní ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀ ní àkókò tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bikoṣe ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o pa ẹran irekọja na li aṣalẹ, nigba ìwọ-õrùn, li akokò ti iwọ ti ilẹ Egipti jade wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
bí kò ṣe ibi tí yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀, níbẹ̀ ni ki ẹ ti ṣe ìrúbọ ìrékọjá náà ní ìrọ̀lẹ́ nígbà tí òòrùn bá ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránti ìgbà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.