Deuteronomy 17:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, tí ẹ bá gbà á, tí ẹ sì ń gbé inú rẹ̀, tí ẹ bá wí nígbà náà pé, ‘A óo fi ẹnìkan jọba lórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí wọ́n yí wa ká,’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ti iwọ ba si gbà a, ti iwọ ba si joko ninu rẹ̀, ti iwọ o si wipe, Emi o fi ọba jẹ lori mi, gẹgẹ bi gbogbo awọn orilẹ-ède ti o yi mi ká;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí OLÚWA Ọlọ́run yín yóò fún un yín, tí ẹ sì ti gba ilẹ̀ náà, tí ẹ sì ń gbé inú un rẹ̀, tí ẹ sì wá sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a yan ọba tí yóò jẹ lé wa lórí bí i ti àwọn orílẹ̀ èdè tí ó yí wa ká.”