Deuteronomy 17:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí ọkunrin kan tabi obinrin kan láàrin àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín bá ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA Ọlọrun yín, nípa pé ó da majẹmu rẹ̀,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi a ba ri lãrin nyin, ninu ibode rẹ kan ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ọkunrin tabi obinrin ti nṣe nkan buburu li oju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni rire majẹmu rẹ̀ kọja,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó ń gbé láàrin yín ní èyíkéyìí ìlú wọ̀n-ọn-nì, tí OLÚWA fún un yín bá ń ṣe ibi ní ojú OLÚWA Ọlọ́run yín, ní ríré májẹ̀mú rẹ̀ kọjá,