Deuteronomy 18:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Gbogbo ẹ̀yà Lefi ni alufaa, nítorí náà wọn kò ní bá àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù pín ilẹ̀. Ninu ọrẹ fún ẹbọ sísun, ati àwọn ọrẹ mìíràn tí àwọn eniyan Israẹli bá mú wá fún OLUWA, ni àwọn ẹ̀yà Lefi yóo ti máa jẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
AWỌN alufa, awọn ọmọ Lefi, ani gbogbo ẹ̀ya Lefi, ki yio ní ipín tabi iní pẹlu Israeli: ki nwọn ki o ma jẹ ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, ati iní rẹ̀ ni ki nwọn ki o ma jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, àní gbogbo ẹ̀yà Léfì, wọn kì yóò ní ìpín tàbí ogún láàrin Ísírẹ́lì, wọn yóò máa jẹ nínú ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe sí OLÚWA, nítorí òun ni ogún un tiwọn.