Deuteronomy 18:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bíi ti ọjọ́ tí ẹ péjọ ní òkè Horebu tí ẹ bẹ OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sọ fún mi pé, ‘Má jẹ́ kí á gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa mọ́, tabi kí á rí iná ńlá yìí mọ́; kí á má baà kú.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ bère lọwọ OLUWA Ọlọrun rẹ ni Horebu li ọjọ́ ajọ nì, wipe, Máṣe jẹ ki emi tun gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun mi mọ́, bẹ̃ni ki emi ki o má tun ri iná nla yi mọ́; ki emi ki o mà ba kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí ni ohun tí ìwọ béèrè lọ́wọ́ OLÚWA Ọlọ́run rẹ ní Hórébù ní ọjọ́ àjọ, nígbà tí ìwọ wí pé, “Kí àwa má ṣe gbọ́ ohùn OLÚWA Ọlọ́run wa tàbí rí iná ńlá yìí mọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò kú.”