Deuteronomy 18:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ohun tí yóo jẹ́ ti àwọn alufaa lára ẹran tí àwọn eniyan bá fi rúbọ nìyí, kì báà jẹ́ akọ mààlúù tabi aguntan ni wọ́n wá fi rúbọ, wọn yóo fún alufaa ní apá ati ẹ̀rẹ̀kẹ́ mejeeji, ati àpòlùkú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyi ni yio si ma jẹ́ ipín awọn alufa lati ọdọ awọn enia wá, lati ọdọ awọn ti o ru ẹbọ, iba ṣe akọ-malu tabi agutan, ki nwọn ki o si fi apa fun alufa, ati ẹrẹkẹ mejeji ati àpo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo èyí ni yóò jẹ́ ìpín àwọn àlùfáà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó fi akọ màlúù tàbí àgùntàn rúbọ; wọn yóò fi èjìká àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ méjèèjì àti gbogbo inú fún àlùfáà.