Deuteronomy 2:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Hori ni wọ́n ń gbé òkè Seiri tẹ́lẹ̀ rí, ṣugbọn àwọn ọmọ Esau ti gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì ti pa wọ́n run. Wọ́n bá tẹ̀dó sórí ilẹ̀ àwọn ọmọ Hori gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli náà ti tẹ̀dó sórí ilẹ̀ tí wọ́n gbà, tí OLUWA fún wọn.)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Hori pẹlu ti ngbé Seiri rí, ṣugbọn awọn ọmọ Esau tẹle wọn, nwọn si run wọn kuro niwaju wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn; gẹgẹ bi Israeli ti ṣe si ilẹ-iní rẹ̀, ti OLUWA fi fun wọn.)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Hórì gbé ní Séírì kí àwọn ọmọ Ísọ̀ tó lé wọn kúrò níwájú wọn, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, (wọ́n tẹ̀dó sí àyè wọn) gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ṣe ní ilẹ̀ tí OLÚWA yóò fún wọn ní ìní wọn.