Deuteronomy 2:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn ọdún mejidinlogoji gbáko tí a ti kúrò ní Kadeṣi Banea, ni a tó kọjá odò Seredi, títí tí gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun ún jà ninu ìran náà fi run tán patapata, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti búra pé yóo rí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ìgba ti awa fi ti Kadeṣi-barnea wá, titi awa fi gòke odò Seredi lọ, o jẹ́ ọgbọ̀n ọdún o le mẹjọ; titi gbogbo iran awọn ologun fi run kuro ninu ibudó, bi OLUWA ti bura fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó gbà wá ní ọdún méjìdínlógójì (38) kí ó tó di wí pé a la àfonífojì Sérédì kọjá láti ìgbà tí a ti kúrò ní Kadesi Báníyà. Nígbà náà gbogbo ìran àwọn tí ó jẹ́ jagunjagun láàrin àwọn ènìyàn náà ti ṣègbé kúrò láàrin àwọn ènìyàn náà ní àsìkò yìí bí OLÚWA ti búra fún wọn.