Deuteronomy 2:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ dìde, ẹ bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò yín, kí ẹ sì ré àfonífojì Anoni kọjá. Mo ti fi Sihoni, ọba Heṣiboni, ní ilẹ̀ àwọn ará Amori, le yín lọ́wọ́, àtòun ati ilẹ̀ rẹ̀. Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí bá a jagun, kí ẹ sì máa gba ilẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ dide, ẹ mú ọ̀na nyin pọ̀n, ki ẹ si gòke odò Arnoni: wò o, emi fi Sihoni ọmọ Amori, ọba Heṣboni lé ọ lọwọ, ati ilẹ rẹ̀: bẹ̀rẹsi gbà a, ki o si bá a jagun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ gbáradì, kí ẹ sì kọjá odò Ánónì. Kíyèsi, Mo ti fi Ṣíhónì ará Ámórì, ọba Héṣíbónì àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Ẹ bá ilẹ̀ náà jagun kí ẹ sì gbà á.