Deuteronomy 2:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
bí àwọn ọmọ Esau, tí wọn ń gbé Seiri ati àwọn ará Moabu tí wọn ń gbé Ari, ti ṣe fún mi, títí tí n óo fi kọjá odò Jọdani, lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun wa ti fi fún wa.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi awọn ọmọ Esau ti ngbé Seiri, ati awọn ara Moabu ti ngbé Ari, ti ṣe si mi; titi emi o fi gòke Jordani si ilẹ ti OLUWA Ọlọrun wa fi fun wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Éṣáù tí ó ń gbé ní Séírì àti àwọn ará Móábù tí ó ń gbé ní Árì, ti gbà wá láàyè títí a fi la Jọ́dánì já dé ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run wa yóò fún wa.”