Deuteronomy 2:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
A gba àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ nígbà náà, a sì run wọ́n, ati ọkunrin, ati obinrin, ati àwọn ọmọ wọn. A kò dá ohunkohun sí,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awa si kó gbogbo ilu rẹ̀ ni ìgba na, awa si run awọn ọkunrin patapata, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ, ni gbogbo ilu; awa kò jẹ ki ọkan ki o kù:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, gbogbo ìlú wọn ni a kó tí a sì pa wọ́n run pátapáta tọkùnrin, tobìnrin àti gbogbo ọmọ wọn. A kò sì dá ẹnikẹ́ni sí.