Deuteronomy 2:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ ranti bí OLUWA Ọlọrun yín ti bukun yín ninu gbogbo ohun tí ẹ dáwọ́lé, ó sì ti tọ́jú yín ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀ ń rìn kiri ninu aṣálẹ̀ ńláńlá yìí. Ó ti wà pẹlu yín láti ogoji ọdún sẹ́yìn wá, ohunkohun kò sì jẹ yín níyà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ ti bukún ọ ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo: o ti mọ̀ ìrin rẹ li aginjù nla yi: li ogoji ọdún yi OLUWA Ọlọrun rẹ ti mbẹ pẹlu rẹ; ọdá ohun kan kò dá ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA Ọlọ́run yín ti bùkún un yín nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ yín. Ó ti mójú tó ìrìnàjò yín nínú ihà ńlá yìí. OLÚWA Ọlọ́run yín wà pẹ̀lú u yín ní ogojì ọdún wọ̀nyí, débi pé ẹ̀yin kò ṣaláìní ohunkóhun.