Deuteronomy 20:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn kí ẹ dá àwọn obinrin ati àwọn ọmọ wọn sí, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ati gbogbo dúkìá yòókù tí ó wà ninu ìlú náà, kí ẹ kó gbogbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín, kí ẹ máa lo gbogbo dúkìá àwọn ọ̀tá yín tí OLUWA Ọlọrun yín ti fun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ ati ohun-ọ̀sin, ati ohun gbogbo ti mbẹ ni ilu na, ani gbogbo ikogun rẹ̀, ni ki iwọ ki o kó fun ara rẹ; ki iwọ ki o si ma jẹ ikogun awọn ọtá rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ti obìnrin, àwọn ọmọdé, ohun ọ̀sìn àti gbogbo ohun tí ó kù nínú ìlú náà, o lè mú ìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìkógún fún ara rẹ. O sì lè lo ìkógún tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ta rẹ.