Deuteronomy 20:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí wọ́n má baà kọ yín ní ìkọ́kúkọ̀ọ́, kí ẹ má baà máa ṣe oríṣìíríṣìí àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ń bọ àwọn oriṣa wọn, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki nwọn ki o má ba kọ́ nyin lati ma ṣe bi gbogbo iṣẹ-irira wọn, ti nwọn ti nṣe si awọn oriṣa wọn; ẹnyin a si ṣẹ̀ bẹ̃ si OLUWA Ọlọrun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kọ́ ọ láti tẹ̀lé gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe nínú sísin àwọn ọlọ́run wọn, ìwọ yóò sì sẹ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ.