Deuteronomy 20:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
‘Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan Israẹli, tí ẹ̀ ń lọ sí ojú ogun lónìí láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àyà yín já, ẹ̀rù kò sì gbọdọ̀ bà yín, ẹ kò gbọdọ̀ wárìrì tabi kí ẹ jẹ́ kí jìnnìjìnnì dà bò yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si wi fun wọn pe, Gbọ́, Israeli, li oni ẹnyin sunmọ ogun si awọn ọtá nyin: ẹ máṣe jẹ ki àiya nyin ki o ṣojo, ẹ máṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe warìri, bẹ̃ni ẹ má si ṣe fòya nitori wọn;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
yóò sì wí pé, “Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀ta rẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù; ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi àyè fún ìjayà níwájú u wọn.