Deuteronomy 21:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ bọ́ aṣọ ẹrú rẹ̀ sílẹ̀, kí ó wà ní ilẹ̀ yín, kí ó sì máa ṣọ̀fọ̀ baba ati ìyá rẹ̀ fún odidi oṣù kan. Lẹ́yìn náà ẹ lè wọlé tọ̀ ọ́, kí ẹ sì di tọkọtaya.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si bọ́ aṣọ igbẹsin rẹ̀ kuro lara rẹ̀, ki o si joko ninu ile rẹ, ki o sọkun baba rẹ̀, ati iya rẹ̀ li oṣù kan tọ̀tọ: lẹhin ìgba na ki iwọ ki o wọle tọ̀ ọ, ki o si ma ṣe ọkọ rẹ̀, on a si ma ṣe aya rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kí o sì mú aṣọ tí ó wọ̀ nígbà tí ó di ìgbékùn sí ẹ̀gbẹ́ kan. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ń gbé ilé rẹ tí ó sì ti sọ̀fọ̀ baba àti ìyá rẹ̀ fún odidi osù kan, nígbà náà ni o lè tọ̀ ọ́ lọ kí o sì ṣe ọkọ rẹ̀ kí ó jẹ́ aya rẹ.