Deuteronomy 21:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí ẹnìkan bá bí ọmọkunrin kan, tí ó jẹ́ aláìgbọràn ati olórí kunkun ọmọ, tí kì í gbọ́, tí kì í sì í gba ti àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n bá a wí títí, ṣugbọn tí kò gbọ́,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ọkunrin kan ba lí ọmọkunrin kan ti o ṣe agídi ati alaigbọran, ti kò gbà ohùn baba rẹ̀ gbọ́, tabi ohùn iya rẹ̀, ati ti nwọn nà a, ti kò si fẹ́ gbà tiwọn gbọ́:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ọkùnrin kan bá ní aláìgbọ́ràn tàbí ọlọ̀tẹ̀ ọmọ tí kò gbọ́rọ̀ sí baba àti ìyá rẹ̀ tí kò sì ní í gbà tí wọ́n bá ń bá a wí,