Deuteronomy 21:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
kí wọ́n mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù náà lọ sí àfonífojì tí ó ní odò tí ń ṣàn, tí ẹnikẹ́ni kò gbin ohunkohun sí rí, kí wọ́n sì lọ́ ọ̀dọ́ mààlúù náà lọ́rùn pa níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki awọn àgba ilu na ki o mú ẹgbọrọ abo-malu na sọkalẹ wá, si afonifoji ti o ní omi ṣiṣàn kan, ti a kò ro ti a kò si gbìn, ki nwọn ki o si ṣẹ́ ọrùn ẹgbọrọ abomalu na nibẹ̀ li afonifoji na:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kí wọn sìn ín wá sí àfonífojì tí a kò ì tíì ro tàbí gbìn àti ibi tí odò ṣíṣàn wà. Níbẹ̀ ní àfonífojì wọn yóò kán ọrùn ẹgbọ̀rọ̀ màlúù.