Deuteronomy 21:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, bá wọn lọ pẹlu; nítorí àwọn ni OLUWA Ọlọrun yín yàn láti máa ṣe alufaa ati láti máa súre fún àwọn eniyan ní orúkọ OLUWA; ati pé àwọn ni OLUWA Ọlọrun yàn láti parí àríyànjiyàn ati ẹjọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn alufa, awọn ọmọ Lefi yio si sunmọtosi; nitoripe awọn ni OLUWA Ọlọrun rẹ yàn lati ma ṣe iṣẹ-ìsin fun u, ati lati ma sure li orukọ OLUWA; nipa ọ̀rọ wọn li a o ti ma wadi ọ̀ran iyàn ati ọ̀ran lilù:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn àlùfáà, ọmọ Léfì yóò wá ṣíwájú, nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún un àti láti bùkún ní orúkọ OLÚWA àti láti parí gbogbo ẹjọ́ àríyànjiyàn àti ọ̀rọ̀ ìlú.