Deuteronomy 22:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn yóo sì gba ọgọrun-un ìwọ̀n ṣekeli fadaka lọ́wọ́ rẹ̀ fún baba ọmọbinrin náà bíi owó ìtanràn; nítorí pé ó ti bá ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin Israẹli lórúkọ jẹ́. Obinrin náà yóo sì tún jẹ́ iyawo rẹ̀, kò sì gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki nwọn ki o si bù ọgọrun ṣekeli fadakà fun u, ki nwọn ki o si fi i fun baba ọmọbinrin na, nitoriti o bà orukọ wundia kan ni Israeli jẹ́: ki on ki o si ma ṣe aya rẹ̀; ki o máṣe kọ̀ ọ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò sì gba ìtanràn ọgọ́rùn ún ṣékélì owó fàdákà fún baba ọmọbìnrin náà, nítorí ọkùnrin yìí ti fi orúkọ búburú fún wúndíá Ísírẹ́lì. Yóò sì máa ṣe ìyàwó rẹ̀; kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ayé e rẹ̀.