Deuteronomy 22:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn yóo fa obinrin náà lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé baba rẹ̀, àwọn ọkunrin ìlú yóo sì sọ ọ́ ní òkúta pa, nítorí pé ó ti hu ìwà òmùgọ̀ ní Israẹli níti pé ó ṣe àgbèrè ní ilé baba rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ibi yìí kúrò láàrin yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ki nwọn ki o mú ọmọbinrin na wá si ẹnu-ọ̀na ile baba rẹ̀, ki awọn ọkunrin ilu rẹ̀ ki o sọ ọ li okuta pa: nitoriti o hù ìwa-buburu ni Israeli, ni ṣiṣe àgbere ninu ile baba rẹ̀: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
wọn yóò mú wá sí ẹnu ọ̀nà ilé baba rẹ̀ níbẹ̀ sì ni àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò ti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ó ti ṣe ohun ìtìjú ní Isírẹ́lì nípa ṣíṣe aṣẹ́wó nígbà tí ó wà nílé baba rẹ̀. Ẹ ní láti pọ ohun búburú kúrò láàrin yín.