Deuteronomy 22:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ẹ mú àwọn mejeeji jáde wá sí ẹnubodè ìlú, kí ẹ sì sọ wọ́n ní òkúta pa. Ẹ̀ṣẹ̀ ti obinrin ni pé, nígbà tí wọ́n kì í mọ́lẹ̀ láàrin ìlú, kò pariwo kí aládùúgbò gbọ́. Ẹ̀ṣẹ̀ ti ọkunrin ni pé, ó ba àfẹ́sọ́nà arakunrin rẹ̀ jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ibi yìí kúrò láàrin yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ ki ẹnyin ki o mú awọn mejeji wá si ẹnu-bode ilu na, ki ẹnyin ki o si ṣo wọn li okuta pa; eyi ọmọbinrin nitoriti kò kigbe, nigbati o wà ni ilu; ati eyi ọkunrin nitoriti o tẹ́ aya ẹnikeji rẹ̀ logo: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ìwọ yóò mú àwọn méjèèjì lọ sí ẹnu ibodè ìlú náà kí o sì sọ wọ́n ní ókúta pa nítorí ọmọbìnrin náà wà ní ìlú kò sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àti ọkùnrin náà nítorí ó ba ìyàwó ọkùnrin mìíràn jẹ́. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrin rẹ.