Deuteronomy 22:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Tí ẹ bá kọ́ ilé titun, ẹ níláti ṣe ìgbátí sí òrùlé rẹ̀ yípo, kí ẹ má baà wá di ẹlẹ́bi bí ẹnikẹ́ni bá jábọ́ láti orí òrùlé yín, tí ó sì kú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iwọ ba kọ ile titun kan, ki iwọ ki o ṣe igbáti si orule rẹ, ki iwọ o má ba mú ẹ̀jẹ wá sara ile rẹ, bi ẹnikan ba ti ibẹ̀ ṣubu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí o bá kọ́ ilé túntún, mọ odi yí òrùlé rẹ̀ ká nítorí kí o má baà mú ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ wá sórí ilẹ̀ rẹ bí ẹnikẹ́ni bá ṣubú láti òrùlé.