Deuteronomy 23:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí olukuluku yín ní ọ̀pá kan, tí yóo máa dì mọ́ ara ohun ìjà rẹ̀, tí ó lè fi gbẹ́lẹ̀ nígbà tí ó bá fẹ́ yàgbẹ́; nígbà tí ó bá sì yàgbẹ́ tán, ọ̀pá yìí ni yóo fi wa erùpẹ̀ bò ó mọ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ ki o si ní ìwalẹ kan pẹlu ohun-ìja rẹ; yio si ṣe, nigbati iwọ o ba gbọnsẹ lẹhin ibudó, ki iwọ ki o fi wàlẹ, ki iwọ ki o si yipada, ki o bò ohun ti o ti ara rẹ jade:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò mú igi pẹ̀lú ohun ìjà rẹ àti nígbà tí o bá dẹ ara rẹ lára tán, gbẹ́ kòtò kí o sì bo ìgbẹ́ rẹ.