Deuteronomy 23:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín wà pẹlu yín ninu àgọ́ láti gbà yín là, ati láti jẹ́ kí ọwọ́ yín tẹ àwọn ọ̀tá yín. Nítorí náà, àgọ́ yín níláti jẹ́ mímọ́, kí OLUWA má baà rí ohunkohun tí ó jẹ́ àìmọ́ láàrin yín, kí ó sì yipada kúrò lọ́dọ̀ yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ nrìn lãrin ibudó rẹ, lati gbà ọ, ati lati fi awọn ọtá rẹ fun ọ; nitorina ki ibudó rẹ ki o jẹ́ mimọ́: ki on ki o máṣe ri ohun aimọ́ kan lọdọ rẹ, on a si pada lẹhin rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ń rìn láàrin àgọ́ láti dáàbò bò ọ́ àti láti fi àwọn ọ̀taà rẹ lé ọ lọ́wọ́. Àgọ́ ọ rẹ ní láti jẹ́ mímọ́, nítorí kí ó má ba à rí ohun àìtọ́ láàrin yín kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ ọ yín.