Deuteronomy 23:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọkunrin tabi obinrin kankan kò gbọdọ̀ mú owó tí ó bá gbà ní ibi àgbèrè ṣíṣe wá sinu ilé OLUWA láti san ẹ̀jẹ́kẹ́jẹ̀ẹ́ tí ó bá jẹ́, nítorí pé, àgbèrè ṣíṣe jẹ́ ohun ìríra níwájú OLUWA Ọlọrun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ kò gbọdọ mú owo ọ̀ya àgbere, tabi owo ajá, wá sinu ile OLUWA Ọlọrun rẹ fun ẹjẹ́kẹjẹ: nitoripe irira ni, ani awọn mejeji si OLUWA Ọlọrun rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
O kò gbọdọ̀ mú owó iṣẹ́ panṣágà obìnrin tàbí ọkùnrin wá sí ilé OLÚWA Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́ kankan; nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ korìíra àwọn méjèèjì.