Deuteronomy 23:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ẹ bá yá àlejò ní nǹkan, ẹ lè gba èlé, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ yá arakunrin yín ní ohunkohun kí ẹ sì gba èlé, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun yín ninu ohun gbogbo tí ẹ bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Alejò ni ki iwọ ki o ma wín fun elé; ṣugbọn arakunrin rẹ ni ki iwọ ki o máṣe win fun elé: ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le ma bukún ọ ninu ohun gbogbo ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé, ni ilẹ na nibiti iwọ nlọ lati gbà a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
O lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí kí OLÚWA Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.