Deuteronomy 23:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà tí ẹ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò gbọdọ̀ má san ẹ̀jẹ́ náà, nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ yín, yóo sì di ẹ̀ṣẹ̀ sí yín lọ́rùn bí ẹ kò bá san án.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iwọ ba jẹ́jẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o máṣe fàsẹhin lati san a: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ yio bère rẹ̀ nitõtọ lọwọ rẹ; yio si di ẹ̀ṣẹ si ọ lọrùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí o bá jẹ́jẹ̀ẹ́ fún OLÚWA Ọlọ́run rẹ, má ṣe lọ́ra láti san án, nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ ọ rẹ, o sì máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.