Deuteronomy 23:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ẹ bá ń kọjá lọ ní oko ọkà ẹlòmíràn, tí wọn kò tíì kórè, ẹ lè fi ọwọ́ ya ìwọ̀nba tí ẹ lè jẹ, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ fi dòjé gé ọkà ọlọ́kà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iwọ ba dé inu oko-ọkà ẹnikeji rẹ, njẹ ki iwọ ki o ma fi ọwọ́ rẹ yà ṣiri rẹ̀; ṣugbọn iwọ kò gbọdọ yọ doje si ọkà ẹnikeji rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí o bá wọ inú oko ọkà aládùúgbò rẹ, o lè fi ọwọ́ rẹ ya sírì rẹ̀, ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ki dòjé bọ ọkà tí ó dúró.