Deuteronomy 23:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ará Amoni ati Moabu kankan kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ, arọmọdọmọ wọn títí dé ìran kẹwaa kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ Ammoni tabi ọmọ Moabu kan ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA; ani dé iran kẹwa enia wọn kan ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA lailai:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí Ámónì tàbí Móábù tàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ wọn má ṣe wọ ìpéjọ OLÚWA, pàápàá títí dé ìran kẹ̀wàá.