Deuteronomy 24:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí ọkunrin kan bá fẹ́ iyawo, tí iyawo náà kò bá wù ú mọ́ nítorí pé ó rí ohun àléébù kan ninu ìwà rẹ̀ tí kò tẹ́ ẹ lọ́rùn; tí ó bá já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tí obinrin náà jáde kúrò ní ilé rẹ̀, tí obinrin náà sì bá tirẹ̀ lọ;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
BI ọkunrin kan ba fẹ́ obinrin kan, ti o si gbé e niyawo, yio si ṣe, bi obinrin na kò ba ri ojurere li oju ọkunrin na, nitoriti o ri ohun alebù kan lara rẹ̀: njẹ ki o kọ iwé ikọsilẹ fun obinrin na, ki o fi i lé e lọwọ, ki o si rán a jade kuro ninu ile rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ obìnrin kan ní ìyàwó tí ó wá padà bà á nínú jẹ́ nítorí ó rí ohun àìtọ́ kan nípa rẹ̀, tí ó sì kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ si i, fi fún un kí ó sì lọ jáde kúrò ní ilé è rẹ,