Deuteronomy 24:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà tí ẹ bá ń kórè ọkà ninu oko yín, tí ẹ bá gbàgbé ìdì ọkà kan sinu oko, ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ gbé e. Ẹ fi sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn aláìní baba ati àwọn opó, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iwọ ba kore rẹ li oko rẹ, ti iwọ ba si gbagbé ití-ọkà kan silẹ ninu oko, ki iwọ ki o máṣe pada lọ mú u: ki o le ma jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó: ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le ma busi i fun ọ, ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ tí o sì fojú fo ìtí kan, má ṣe padà lọ mú u. Fi í kalẹ̀ fún àwọn àlejò, aláìní baba àti opó, kí OLÚWA Ọlọ́run rẹ lè bùkún fún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ.