Deuteronomy 24:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ẹ bá ti ká èso olifi yín, ẹ kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti ká àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn aláìní baba ati àwọn opó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iwọ ba ngún igi olifi rẹ, ki iwọ ki o máṣe tun pada wò ẹka rẹ̀: ki eyinì ki o jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí o bá ń gun igi ólífì lára àwọn igi i rẹ, má ṣe padà lọ sí ẹ̀ka náà ní ìgbà kejì. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó.